Igbagbo – Sola Allyson

 

Igba miran, o ma nse mi bii ki n pada s’eyin
Igba miran, o ma nse mi bii ki n jowo re
Igba t’iji aye ba n ja bii ki n pada s’eyin
Igba t’okan mi po ruru bii ki n jowo re

Sugbon, mo mo iwo ni eni ti kii ko ni sile
Beeni mo mo, iwo ni eni ti n s’olododo
Sugbon mo gba iwo ni eni ti kii koni sile
Beeni mo gba iwo ni eni to s’olododo

Igbagbo mi duro l’ori ododo re
Iwo l’apata ayeraye ibi i sadi mi
Bi okan mi po ruru, ko le pa ise re da lai lai
Iwo s’olododo, mo si mo oo ni alaanu
Igbagbo mi ro mo o
Iwo ni agbara mi
Oke ni mo f’okan si ibi ti iran’wo n gbe wa

Funmi lokun at’oke wa ki n maa se pada s’ehin
ki n ma sise ninu iriri, ki n ma se jowo re

Tori, mo mo iwo ni eni ti kii ko ni sile
Beeni mo mo, iwo ni eni to s’olododo
Tori, mo gba iwo ni eni ti kii koni sile
Beeni mo gba iwo ni eni to s’olododo

Iriri aye a maa fe so eniyan d’eni onigbagbo
Sibe, mio gbekele ounkan leyin agbara re
Ogbon ori eniyan o le ro ja eto tooni, lai lai
Koda b’okan mi se iye meji, ileri t’ose oduro
Abrahamu, Sarah won r’eri looto tori o n dabi pe yeye ni
Si be won d’eni ti o to si fun ibukun pipe

Funmi lokun at’oke wa Iwo ni alati lehin
ki n ma subu, ki n laajo yi ja
Ki n mase jowo re

Tori, mo mo iwo ni eni ti kii ko ni sile
Beeni mo mo, iwo ni eni to s’olododo
Tori, mo gba iwo ni eni ti kii koni sile
Beeni mo gba iwo ni eni to s’olododo /3x

Top