Mojuba – Sola Allyson

 

Mojuba oba
Mojuba oba
Iba eledumare to ni gbogbo ogo
Aterere ka ri aye, olorun awon omo ogun
Mojuba oba /2x

Verse 1

Iba eledumare, oba to ni gbogbo aye
Eni nla ti n be l’ori ti ti lai lai lai
Emi mi b’ola fun o ooo
Lati ogbon iseda mi ni
Mo yika otun mo yi t’osi, mo gba ruburubu
F’eni naa alapole ju lo, eni ayeraye

Iwo lo ti n be
Iwo lo si ma be
Lehin re ko si mo, oba ti ti lai
Mosin o, mosin o, mosin o, mosin o
Lati ogbon emi mi
Eni naa, oba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n bu ola fun o

Chorus

Mojuba oba
Mojuba oba
Iba eledumare to ni gbogbo ogo
Aterere ka ri aye, olorun awon omo ogun
Mojuba oba /2x

Verse 2

Iwo ni Oba ti o le pa p’ohunda lai lai
Oba to ti wa ti o si ma be ti ti ti
Aye mi o ma fi’bukun fun oruko re
Ileke ola, ipinle oye, opin gbogbo ola
Gbogbo ise re ni o mo yin o, a n pe o l’oba

Iwo ni alaanu to f’ebun se mi l’oso
Otu fi ogo die bu tan, o fun mi l’ade
Odo re naa ni gbogbo ogo naa pada si oluwa
Eni naa, oba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n bu ola fun o

Call & Response

Gbogbo ise re ati emi ooo
A n bu ola fun o

Awon oun ti ari ati awon ti ao ri
A n bu ola fun o

Loke orun lohun, l’agbede meji, ile t’ante
Ogo ni f’oruko re
A n bu ola fun o

Iwo ni onike to po, olola to po, alaanu to po
A n bu ola fun o

Ko s’ede naa ni gbogbo aye ti iro ogo re kii bu yo
A n bu ola fun o

Iran okun b’ola fun o
Osa naa b’ola fun o, gbogbo ise
A n bu ola fun o

Gbogbo ede, gbogbo ijoba lo n wa riri fun oruko re
A n bu ola fun o

Gbogbo ise re ati emi
A n bu ola fun o

Top